AYE OPE YO By Adeyinka Alaseyori
AYE OPE YO is a Yoruba worship song that reminisce different obstacles life unleash at different time but the faithfulness of God has also been sufficient despite all. It is an inspirational song that will allow to think deep and see reasons to praise God.
Click the below button to download the song now (6mb)
LYRICS
E se Aye ope yo
E se toripe aye ope yo
E se Aye ope yo o
Emi awon woli o
Aye ope pada yo
Gbogbo ale ta sun ta ji, aye ope kan ni
Gbogbo igba ta ba sun lale,
Ta o ranti lati Gbadura, e o gba ki ile wo pa wa lat’oju orun wa saye
Aimoye igba ta ma ji, ta ma ma sare pe a ti late Otun d’abo bo wa o
O f’aye gba satani lati yo ayo isegun lori aye wa
Aye ope pada yo
L’ati ile loti mu wa o mu wa joko pelu awon omo alade
O f’aye gba wa laarin awon omo alade ilu wa
A wa n’soro nibi giga
Mo ki o toripe aye ope yo o
Emi awon woli o
Aye ope pada yo
Melo leebu awon eyan lara wa, to gbon danu Pelu eri
Melo ni awa to ti rope,
Ohun rere o le ti Inu wa jade,
To funrugbin ohun rere sinu wa to Tun jeyo
Mo ki o toripe aye ope yo o
After all we’ve been through
Aye ope pada yo
Igba kan ri won da’so fun o ko to di pe awon Omo to bi ri aso wo ni o
Igba kan ri won da’so fun o ko to di pe
Awon Omo to bi ninu re r’aso bo ihoho won
Igba kan ri o pelu awon ton gbe kiri
Lati ma toro Owo loju titi ese oloore toripe
Aye ope pada yo
Ah
Aye ope yo
O se aye ope yo
O se Aye ope yo o
Emi awon woli o
Aye ope pada yo
Igba ti o si nkankan se pe aye ope le yo
Igba ti gbogbo ohun gbogbo doju ru se pe aye Ope tun le yo
Ki la o ni dupe fun nigbati aye ope ti yo o
After all we’ve been through
Aye ope pada yo
Igba kan ri won pe o l’agan o
Sugbon lowolowo o pada gbomo jo
Igba kan ri won sa fun o lawujo awon eyan gidi
Sugbon lowolowo o ti joko pelu awon olola
Igba kan ri oo won ti write e off pe ohun rere o le Tinu re
Jade wa, won ti write e off pe ohun rere o Le tinu re jade wa
Sugbon emi Inu awon woli,
Agbanilagbatan Agbani ma gbowo,
Arugbo ojo jojo ninu eni to Fun ojo loju lati ma yo
Ninu re ni ojo tin je ojo o, ojo to yo ninu re lo Jo
Oju ton riran ninu okunkun birimu birimu
Eni nla ton se ohun nla
Eni nla ton se ohun ari tokasi
Eyan a ma gbe oyun sinu, fun gbogbo osu mesan, iwo na ni abo won
Eni aye de oyun mo ninu fun odun meji,
Meeta, meerin, maarun, meefa logan to ba o pade
O tu won sile lai gba ohunkohun rara
Emi awon woli o
O se o, toripe aye ope pada yo
Aimoye oloyun to yo ninu ewu
Aimoye trailer to subu Lu motor
O je a si lara won
A o gbe ounje pari, a le mai si nibi toye Ka wa
Sugbon a dupe ibi te ba wa de
Kinihun eya Judah aye ope pada yo
Ohun gbogbo lo se fun mi
Ohun gbogbo lo se fun mi
Ki lo ti se fun mi ko si o
Ohun gbogbo lo se fun mi
O fun mi lomo bi o se o
O fun mi loko fe o se o
Iwo to gbe mi jade lati inu ira
To fo mi laso mo
Iwo to pin okun pupa niya lai se pe
Omi ya lu Awon omo isreali lojo yen
Bawo lo se se, iwo ni o kabiyesi olola, iwo na ni
Ohun gbogbo lo se fun mi
Ohun gbogbo lo se fun mi
Ki lo ti se fun mi ko si o
Ohun gbogbo lo se fun mi
Gbogbo ojo lon d’abo bo mi lon yo mi ninu ewu
Lara ohun to se fun mi ti mi o le so
Ni emi ti mon Mi sinu to o gba lowo mi
Lara ohun to se fun mi ti mi o le so tan ni oju Iriran,
Ese ton rin, owo ton sise,
Eti ton gboran, Speaker to soro jade ninu mi o be o
Ohun gbogbo ma lo se ninu ohun gbogbo
Aimoye ijakadi lile to ja lori oro mi loru moju
Iwo lo se, iwo lo je ohun gbogbo ninu ohun Gbogbo,
Atobi tan o, atoba tan, a to Baba ma pe Enikeni ni Baba
Iwo ni o o o
Oro tin gbe’nu Omo eniyan f’ohun
Oro ton gbe inu ikoko tu asiri won ni gbangba
Oju to ri okunkun ninu okunkun o
Oju to la okunkun loju ninu okunkun birimu Birimu, iwo na ni
Baba mi o o o
A dun f’oro lo, a to ba soro, a to f’ise ogun ran,
A to Baba ma pe Enikeni ni Baba,
Aridunnu mi nigba Ti ibanuje de,
Owo ton gba ibi kuro loju ona Wa, iwo ma ni, iwo ma ni o
Iwo ni, iwo ma ni o
Iwo ni Baba mi o, iwo ni ore mi
Bawo lo se se
Ti igi fi koja lo sinu omi to magnet irin wa sori Omi,
Aake to jabo sinu omi lojo yen igi lo
Fi gbe jade, owo airi re lon sise agbara o
Owo airi re lo se wonder lojo yen
Iwo ni, iwo ma ni
Bawo lo se se
Obinrin onisun eje laarin egbegberun
Eniyan ton Lon, ase jade Lara re Logan lo mo o
O koja lo sorisun isun eje odun mejila, loba gbe Lesekese o,
Awon oni dokita ati babalawo won ti Gba, gbogbo eyan ti gba,
Woli ika ti gba, real woli Ti gba,
Sugbon Logan ti o ba o pade lo rowo Agabara
Bawo lo se se
Iwo ni, iwo lo ye
Odi Jericho, o subu pelu ariwo leekan sooso
Bawo lo se se
Awon omo isreali rin l’aginju fun odidi
Ogoji Odun, bata won o je, aso won o gbo
Iwo ni asiri ton so won di tuntun lojojumo
Bawo lo se se o kabiyesi olola
Bawo lo se se oni wonder ton gbe wonder mi o
Iyanu ton ya aye lenu, bawo lo se se
Oni wonder oni wonder o se o
Emimimo bawo lo se se
Ti iyo kekere fi trace arin omi,
Ko disappear to fi De orisun isale odo mara,
O so di didun, o so di Didun, o so odo mara di didun
Oni wonder oni wonder o se
Jesu oni wonder o se o
Jesu oni wonder o se o
Jesu oni wonder o seun
Eru ton d’eru b’eru o
Eru t’eru ri to sa t’eru o le ba o
Erujeje ton d’eru b’eru o
Eru re ba mi olodu to mo gbogbo are patapata
Ina loju, ina lenu
Gbogbo ara kikida ase
Ibi to ba de l’ase duro si
Ibi to ba si iyanu o ki le sele o
Ninu re ni aragba yamuyamu iyanu ngbe ti o
Le Tan, orisun iyanu, orisun ara, inu re ni
Oni wonder oni wonder o se
Jesu oni wonder o se o
Jesu oni wonder o se o
Jesu oni wonder o se o
Iwo l’ariwo to ta laarin awon egungun gbigbe
Iwo lo so egungun gbigbe di aye ti ori wa orun
Ri Ti orun wa ara won ri ti won o miss ara won
Iwo l’asiri ton gba yitiyiti ninu osumare
Asiri ta wa ta o ri, iwo na ni
E ru, oba eru, oba eru
Eru re to ba o
E ru, oba eru, oba eru
Eru re to ba o
Eru ton d’eru b’eru
Eru t’eru o le ba o
Erujeje t’eru o le ba o
Eru re to ba o
E ru, oba eru, oba eru
Eru re to ba o
Eni ti gbogbo aye binu si, wa ma yonu si
Eru ni o
Eni ti gbogbo aye pada leyin re, wa ma fa mora
Eru ni o
Eni ti gbogbo aye nda lebi, wa ma da won lare
Eru ni o
E ru
Eru re to mi ba o
E ru, oba eru, oba eru
Eru re to ba o
E ru, oba eru, oba eru
Eru re to ba o
Gbogbo eda to ti write off, wa ma si new Chapter fun won
Eru re to mi ba o
E ru, oba eru
Eru re to mi ba o